Ewi | IKILO AGBA | APA KINNI (Yoruba)
Hun-un! Melô lafé kà nínú eyín adípèlé
Melo lafe so
Ohun oju ri nigbo ogboju ode nikabi
Ohun oju ri n'iju, akikanju lole rohin
Ohun oju ri enu oma ni leso

Hun! Oro yi seni nipele
Adia f'omo alaja to nt ’aja nile alájá
O n kiri Aja kiri
Won ni kilo pon seyin,
Ol'eran ogun ni
Won ni kopada sile tori Ògún n se orò
Won kii nilo pe olewu
Sugbon ona abayo kan wa toba fee lo
Won ni ko rubö k'aje lewogba
Won ni ko juba k'ogun ma feran e ya
Oni ohun gangan omo Ògún omo òògùn
Oni kosewu f'omo abore
Kini katise nigbato fariga
Kini kati ro nigbato k'opako s’oro agba
O f'oju bintin oro agba
O f'oju kere agba
Otoju agba mole.

Hun-un!                 

Ojo pofiri omo alaja oma pada wale!
Eyi ko awon ara ile alájá siyonu
Won tusita bi eye leke-leke
Won nwa omo alaja kiri
Nigba t'álé lé
Aja lo pada wale pelu eran enia l'enu
Aja gbeegun enia ha'nu bi eegun eku
Ibanuje dori agba kodo lojo yii
Ariwo gba ile alájá
Gbogbo ilu kan dódó
Eni awifun oba je ogbo
Omo alaja omope agba kii soro lai nidi!
komo pe iriri ati agba omo iya niwon
Ikilo re e o fun eleti didi
Ikilo re e o f'alaigboran
Ejowo ema se p'òrò agba leke
Ema se muwon l'oniro
Ògún oni f'eje gbogbo wa we ooo
Ami ase edumare.


Ojo keeta-Osun Beelu-Odun Egbaa-Leni Merindinlogun
Agogo mokanla owuro.
©Stefan.                                   
OLANREWAJU BOLAJI

Comments

Popular posts from this blog

The First Day Of My Internship - Day One

Almost Almost - Day Three

Hello Readers, Welcome To Diary Section